| ||
Script: ỌSẸ MARUN Laarin ọsẹ kẹrin si ikarun, ọpọlọ yio maa dagbasoke ni kiakia sii, yio si pin si ọna marun ọtọọtọ. Ori jẹ iwọn kan ninu idamẹta gbogbo ara ọmọ inu oyun naa. Ọpọlọ iwaju yio gba aaye ti o pọ fun ara rẹ, yio si di ẹya ti o tobi ju ninu ọpọlọ. Awọn iS̩ẹ ti ọpọlọ iwaju yi wa fun ni ironu, ẹkọ kikọ, iranti nkan, ọrọ sisọ, iriran, igbọran, gbigbe ọwọ tabi ẹsẹ, ati yiyanju ọran ti o S̩oro. | ||
All ages referenced to fertilization, not last menstrual period. |