| ||
Script: Laarin ọjọ mẹta si mẹrin lẹhin idapọ ẹyin ọkunrin ati obirin, ẹyin naa yio maa pin si ọna pupọ, wọn a ri rogodo, a si npe oyun inu naa nisisiyi ni morula. Laarin ọjọ mẹrin si marun, iho kan yio waye laarin awọn ẹyin rogodo wọnyi, a si npe oyun inu naa nisisiyi ni bilasitosisiti. Awọn ẹyin keekeke ti o wa ninu bilasitosisiti yi ni a npe ni akojọpọ ẹyin ti inu, eyiti yio ko ara wọn jọ pọ lati di ori, ara, ati awọn ẹya ara miran ti o S̩e pataki fun idagbasoke ọmọ enia. | ||
All ages referenced to fertilization, not last menstrual period. |