Skip Navigation
The Endowment for Human Development
The Endowment for Human Development
Improving lifelong health one pregnancy at a time.
Donate Now Get Free Videos

Multilingual Illustrated DVD [Tutorial]

The Biology of Prenatal Development




ẸKỌ NIPA IDAGBASOKE ỌMỌ NINU OYUN KI A TO BI I S’AYE

.Yoruba


National Geographic Society This program is distributed in the U.S. and Canada by National Geographic and EHD. [learn more]

Choose Language:
Download English PDF  Download Spanish PDF  Download French PDF  What is PDF?
 

Chapter 40   3 to 4 Months (12 to 16 Weeks): Taste Buds, Jaw Motion, Rooting Reflex, Quickening

Laarin ọsẹ kọkanla si ikejila, iwọn ara ọmọ inu oyun naa yio pọ sii pẹlu iwọn ọgọta ninu ọgọrun.

Ọsẹ kejila ni opin ipele akọkọ ninu mẹta, igba ti obirin fi nloyun.

Awọn ohun ti a fi nse itọwo ounjẹ yio bo gbogbo ayika ẹnu.
Bi a ba bimọ naa tan, awọn ohun itọwo wọnyi yioS̩i wa nipo lori ahọn nikan, ati ni oke ẹnu.

Igbẹ yiya yio bẹrẹ lati bi ọsẹ kejila, yio si tẹsiwaju fun bi ọsẹ mẹfa sii.

Ohun akọkọ tii ma jade lati idi ọmọ inu oyun ati ọmọ ti a S̩ẹS̩ẹ bi ni a npe ni mẹkoniọmu. Ninu rẹ ni a ti le ri awọn ohun ti nmu ounjẹ da, ounjẹ tii mu ni dagbasoke, ati awọn ẹyin keekeke ti ko wulo mọ, eyiti o jade lati inu ẹya ara ti ngbe ounjẹ kaakiri ara.

Ni ọsẹ kejila, gigun ọwọ ti fẹrẹ to iwọn ti o yẹ fun ara. Ẹsẹ ma npọ diẹ sii ki o to gun to bi o ti yẹ fun ara.

Bi a ba yọ ti ẹhin ati oke ori kuro, gbogbo ara ọmọ inu oyun naa ni o ma nfesi, bi a ba rọra fọwọ kan wọn.

Awọn idagbasoke ti o ba ti ẹya akọ tabi abo lọ yio farahan fun igba akọkọ. Fun apẹẹrẹ, ọmọ obirin ma njẹ ẹnu rẹ bakan ju ọmọ ọkunrin lọ.

Yatọ si bi o ti ma nS̩e tẹlẹ ri, bi a ba fọwọkan ẹnu ọmọ inu oyun yi, yio yirapada si ọkankan ibiti a ti fọwọkan-an, yio si la ẹnu rẹ. Iru ifesi bayi ni a npe ni “rutini rifulẹkisi” o si ma ntẹsiwaju lẹhin ti ọmọ naa ba d’aye tan, ninu eyiti i ma ran ọmọ lọwọ lati wa ibiti ori-ọmu iya rẹ wa, nigbati o ba fẹ mu ọmu.

Oju yio maa dagbasoke sii, bi ọra ti nkun gbogbo ẹrẹkẹ, bẹẹ si ni ehin naa yio bẹrẹ sii dagbasoke.

Ni ọsẹ kẹẹdogun, awọn ohun tii ma ndi ẹjẹ lara enia yio farahan, wọn a si maa pọ sii ninu ọra inu egungun. Ibiyi ni a o ti sẹda pupọ ninu ẹjẹ ara ọmọ enia.

Biotilẹjẹpe ọmọ inu oyun ti le gbe ara rẹ lati ọsẹ kẹfa lẹhin ti a loyun rẹ, aboyun ma nmọ, fun igba akọkọ, wipe ọmọ inu oun ngberasọ, laarin ọsẹ kẹrinla si ikejidinloogun. Ninu asa abinibi, a npe eleyi ni gbigberasọ.


Add a Comment

Your Name: Log In 3rd-party login: Facebook     Google     Yahoo

Comment: