WEBVTT 00:00.000 --> 00:02.000 Laarin ọjọ mẹta si mẹrin lẹhin idapọ ẹyin ọkunrin ati obirin, 00:02.033 --> 00:06.333 ẹyin naa yio maa pin si ọna pupọ, wọn a ri rogodo, 00:06.367 --> 00:10.200 a si npe oyun inu naa nisisiyi ni morula. 00:10.233 --> 00:14.733 Laarin ọjọ mẹrin si marun, iho kan yio waye laarin awọn ẹyin rogodo wọnyi, 00:14.767 --> 00:18.833 a si npe oyun inu naa nisisiyi ni bilasitosisiti. 00:18.867 --> 00:20.867 Awọn ẹyin keekeke ti o wa ninu bilasitosisiti yi 00:20.900 --> 00:24.067 ni a npe ni akojọpọ ẹyin ti inu, 00:24.100 --> 00:27.800 eyiti yio ko ara wọn jọ pọ lati di ori, ara, ati awọn ẹya ara miran 00:27.833 --> 00:31.167 ti o S̩e pataki fun idagbasoke ọmọ enia.