Skip Navigation
The Endowment for Human Development
The Endowment for Human Development
Improving lifelong health one pregnancy at a time.
Donate Now Get Free Videos

Multilingual Illustrated DVD [Tutorial]

The Biology of Prenatal Development




ẸKỌ NIPA IDAGBASOKE ỌMỌ NINU OYUN KI A TO BI I S’AYE

.Yoruba


National Geographic Society This program is distributed in the U.S. and Canada by National Geographic and EHD. [learn more]

Choose Language:
Download English PDF  Download Spanish PDF  Download French PDF  What is PDF?
 

The Fetal Period (8 Weeks through Birth)

Chapter 37   9 Weeks: Swallows, Sighs, and Stretches

Akoko fitọsi yi wa titi di igbati a o bi ọmọ naa.

Ni ọsẹ kẹsan, ọmọ inu oyun naa yio bẹrẹ sii mu ika rẹ, o si le gbe omi inu apo ile-ọmọ mi.

Ọmọ inu oyun naa le di nkan mu, o le mi ori rẹ siwaju ati sẹhin, o le la ẹnu rẹ, o le gbe ahọn rẹ, o le poS̩e, osi le na.

Isan-ara ti o wa ni oju, atẹlẹwọ, ati atẹlẹsẹ ma nmọ ọ lara bi a ba fi ọwọ kan wọn.

“Bi a ba rọra fi ọwọ kan gigise,” ọmọ inu oyun yio rọ ibadi rẹ ati orunkun rẹ yio si lẹ ọmọ-ika ẹsẹ rẹ pọ

Ipenpeju ọmọ naa yio bo oju rẹ patapata.

Ninu apoti ifọhun ti o wa ni ọna-ọfun, ifarahan awọn edidi ni yio fihan wipe awọn okun ti a fi nfọhun ti ndagbasoke.

Ni ara ọmọ inu oyun ti o jẹ obirin, a ti le da apo ile-ọmọ mọ, awọn ẹyin ile-ọmọ ti ko i tii dagba tan, ti a npe ni hugonia wa ninu apo ile-ọmọ naa, nibiti wọn ti npin si ọna pupọ.

Awọn ẹya ara ti o wa fun ọmọ bibi yio ma farahan gẹgẹbi ẹya ara ọkunrin tabi ti obirin.

Chapter 38   10 Weeks: Rolls Eyes and Yawns, Fingernails & Fingerprints

Orisirisi awọn idagbasoke ti nwaye laarin ọsẹ kẹsan si ikẹwa yio mu ki ara ọmọ naa o tobi sii bi iwọn marundinlọgọrin ninu ọgọrun.

Ni ọsẹ kẹwa, bi a ba fọwọkan ipenpeju ọmọ naa, yio yi ẹyin-oju rẹ si isalẹ.

Ọmọ inu oyun naa le yan, o le la ẹnu rẹ, ki o si paade.

Ọpọlọpọ ọmọ inu oyun ni maa nmu atanpako wọn ọtun.

Apa kan lara ifun, nibiti ibi-ọmọ wa yio ma wọnu ara pada si inu ikun.

Awọn egungun yio maa le sii.

Eekanna ọwọ ati ti ẹsẹ yio bẹrẹ sii hu jade.

Aami ori ika-ọwọ yio bẹrẹ sii han ni ọsẹ kẹwa lẹhin idapọ ọkunrin ati obirin. Aami yi ni a fi nda enia mọ ni gbigbo ọjọ aye rẹ.

Chapter 39   11 Weeks: Absorbs Glucose and Water

Ni ọsẹ kọkanla, imu ati ete ti yọ jade daradara. Gẹgẹbi oS̩e wa ni awọn ẹya ara yoku, irisi wọn yio ma yipada lati igba de igba, ninu igbesi-aye ọmọ enia naa.

Ifun inu yio bẹrẹ sii fa S̩uga ati omi ti ọmọ inu oyun naa ba gbemi mu.

Biotilẹjẹpe ẹya akọ tabi abo ma nfarahan lati igbati idapọ ẹyin ọkọ ati aya ba ti waye, awọn ẹya ara ti o wa fun ọmọ bibi ni a le damọ bayi, gẹgẹ bi ẹya ti akọ tabi ti abo.


Add a Comment

Your Name: Log In 3rd-party login: Facebook     Google     Yahoo

Comment:
     


Newest  |  Top Rated

1 Comment


rajasree raja
October 2, 2013 at 1:07 am
rajasree raja
thanks for your details
Report
Dislike
Like