Skip Navigation
The Endowment for Human Development
The Endowment for Human Development
Improving lifelong health one pregnancy at a time.
Donate Now Get Free Videos

Multilingual Illustrated DVD [Tutorial]

The Biology of Prenatal Development




ẸKỌ NIPA IDAGBASOKE ỌMỌ NINU OYUN KI A TO BI I S’AYE

.Yoruba


National Geographic Society This program is distributed in the U.S. and Canada by National Geographic and EHD. [learn more]

Choose Language:
Download English PDF  Download Spanish PDF  Download French PDF  What is PDF?
 

Chapter 41   4 to 5 Months (16 to 20 Weeks): Stress Response, Vernix Caseosa, Circadian Rhythms

Ni ọsẹ kẹrindinloogun, ọna kan ti a ngba ki abẹrẹ sinu ikun ọmọ inu oyun ma nmu ifesi kan waye, eyiti nfa ohun kan ti a npe ni noradirẹnalini, tabi norẹpinẹpirini wọ inu ẹjẹ. Ọmọ ti a S̩ẹS̩ẹ bi ati agbalagba paapa ma nse bayi nigbati ohun ajeji kan ba fẹ wọnu ara wọn.

Ninu ẹya ara ti a fi nmi, ọna ti atẹgun ngba wọnu ara ti dagbasoke daradara.

Ohun kan funfun, ti o wa fun aabo, eyiti a npe ni famisi kasehosa, yio bo gbogbo ara ọmọ inu oyun naa. Famisi yi ma ndaabobo awọ-ara kuro lọwọ awọn ohun ti npanilara, eyiti o wa ninu omira ti o wa ni apo ile-ọmọ.

Lati ọsẹ kẹsan, gbigbe ara, mimi atẹgun sinu, ati lilu ọkan yio bẹrẹ sii waye ni ojoojumọ, ilana eyiti a npe ni lilu ti sakediani.

Chapter 42   5 to 6 Months (20 to 24 Weeks): Responds to Sound; Hair and Skin; Age of Viability

Ni ogun ọsẹ, apa kan ninu iho eti, eyiti o jẹ ẹya ara ti igbọran, yio ti tobi to ti agbalagba ninu iho eti ti o ti dagbasoke tan naa. Lati igba yi lọ, ọmọ inu oyun yio maa fesi si oriS̩iriS̩i ariwo.

Irun yio bẹrẹ sii hu lori.

Gbogbo awọ-ara ati ẹya wọn ti wa nipo, pẹlu iho irun ati awọn apo keekeke ti ngbe abẹ awọ-ara.

Ni ọsẹ kọkanleloogun si ikejileloogun lẹhin idapọ, ẹdọforo yio lagbara lati maa mi atẹgun sinu. Ọmọ inu oyun le gbe ile-aye nisinsinyi, nitori pe wiwa laaye ni ode apo ile-ọmọ yio S̩ee S̩e fun awọn ọmọ inu oyun kan. OriS̩iriS̩i awọn aseyọri ninu ẹkọ ilera njẹki o S̩ee S̩e lati mu ẹmi awọn ọmọ ti osu wọn ko pe duro.


Add a Comment

Your Name: Log In 3rd-party login: Facebook     Google     Yahoo

Comment: