Skip Navigation
The Endowment for Human Development
The Endowment for Human Development
Improving lifelong health one pregnancy at a time.
Donate Now Get Free Videos

Multilingual Illustrated DVD [Tutorial]

The Biology of Prenatal Development




ẸKỌ NIPA IDAGBASOKE ỌMỌ NINU OYUN KI A TO BI I S’AYE

.Yoruba


National Geographic Society This program is distributed in the U.S. and Canada by National Geographic and EHD. [learn more]

Choose Language:
Download English PDF  Download Spanish PDF  Download French PDF  What is PDF?
 

Chapter 15   5 Weeks: Cerebral Hemispheres

Laarin ọsẹ kẹrin si ikarun, ọpọlọ yio maa dagbasoke ni kiakia sii, yio si pin si ọna marun ọtọọtọ.

Ori jẹ iwọn kan ninu idamẹta gbogbo ara ọmọ inu oyun naa.

Ọpọlọ iwaju yio gba aaye ti o pọ fun ara rẹ, yio si di ẹya ti o tobi ju ninu ọpọlọ.

Awọn iS̩ẹ ti ọpọlọ iwaju yi wa fun ni ironu, ẹkọ kikọ, iranti nkan, ọrọ sisọ, iriran, igbọran, gbigbe ọwọ tabi ẹsẹ, ati yiyanju ọran ti o S̩oro.

Chapter 16   Major Airways

Ninu ẹya ara ti ngbe atẹgun kaakiri ara, iho ti atẹgun ngba pin si ọna meji, ni apa ọtun ati apa osi, eyi si ni yio so ọna ọfun pọ mọ ẹdọforo.

Chapter 17   Liver and Kidneys

Sakiyesi ẹdọ nla ti o gba aaye ti o pọ ninu ikun, ni abẹ ọkan ti nmi naa.

Kidirin ti yio wa titi aye yio farahan ni ọsẹ karun.

Chapter 18   Yolk Sac and Germ Cells

Ninu apo ẹyin ni awọn yin keekeke fun ọmọ bibi, eyiti a npe ni jamu sẹẹli, wa. Ni ọsẹ karun, awọn ẹyin keekeke wọnyi yio lọ si ẹya ara ti o wa fun ọmọ bibi, eyiti o wa l’ẹgbẹ kidinrin.

Chapter 19   Hand Plates and Cartilage

Bakanna, ni ọsẹ karun, atẹlẹwọ ọmọ inu oyun naa yio bẹrẹ sii farahan, kerekere yio si bẹrẹ si ni farahan lati ọS̩u karun ati aabọ.

Ni bayi, a o S̩akiyesi atẹlẹwọ ti ọwọ osi ati ti ọrun ọwọ, ni ọsẹ karun ati ọjọ mẹfa.

Embryonic Development: 6 to 8 Weeks

Chapter 20   6 Weeks: Motion and Sensation

Ni ọsẹ kẹfa, aaye ti ọpọlọ iwaju gba yio maa tobi sii ni ọna ti o ya ju awọn ẹya ọpọlọ yoku lọ.

Ọmọ inu oyun naa yio bẹrẹ sii ni yi sihin sọhun. Iru yiyi sihin sọhun yi S̩e pataki lati mu ilọsiwaju ba idagbasoke iS̩an ara.

Bi a ba f’ọwọ kan ẹnu rẹ, ọmọ inu oyun naa yio fa ori rẹ mọra lọgan.

Chapter 21   The External Ear and Blood Cell Formation

Eti naa ti nhu jade.

Ni ọsẹ kẹfa, ẹjẹ yio ti maa kojọpọ ninu ẹdọ, ninu ibiti awọn ohun kan ti ma ndaabobo ara lọwọ arun wa. Awọn ohun ti ndaabobo ara wọnyi jẹ koko lara apapọ awọn ẹya ara tii ma ba arun ja lara enia.

Chapter 22   The Diaphragm and Intestines

Ẹran ara ti o wa ni agbedemeji aya ati ikun, eyiti o jẹ ẹran ara ti enia fi nmi, yio ti farahan ni ọsẹ kẹfa.

Apa kan lara ikun yio wu jade fun igba diẹ sinu okun ibi-ọmọ. Ilana yi, eyiti i ma S̩ẹlẹ nigbagbogbo, ni a npe ni ifun yiyọjade ni ara enia. eyi a si maa fi aaye silẹ fun awọn ẹya ara miran ninu ikun.

Chapter 23   Hand Plates and Brainwaves

Ni ọsẹ kẹfa, atẹlẹwọ yio di pẹrẹsẹ.

Ọpọlọ yio ti lagbara lati ronu lati bi ọsẹ karun ati ọjọ meji.

Chapter 24   Nipple Formation

Awọn sonso ori ọmu yio yọ si aya, lẹhin eyiti wọn yio lọ si ibiti o yẹ ki wọn o duro si ni ookan-aya.

Chapter 25   Limb Development

Ni ọsẹ kẹfa ati aabọ, awọn igunpa ọwọ yio ti yanju, aami ori ika ọwọ yio ti maa han, enia si le maa wo ọwọ naa bi o ti nmi.

Dida egungun ara, eyiti a npe ni osifikesan yio bẹrẹ lati ibi egungun ejika, eyiti a npe ni egungun kọla, ati egungun oke ati isalẹ agbọn ẹnu.

Chapter 26   7 Weeks: Hiccups and Startle Response

A o ti sakiyesi wipe ọmọ inu oyun nse osuke, ki o too to ọsẹ keje.

A le S̩akiyesi bi ọmọ inu oyun ti ngbe ẹsẹ rẹ, nigbakugba ti ohun kan ba dẹru baa.

Chapter 27   The Maturing Heart

Ọkan ọmọ naa, eyiti o pin si ọna mẹrin, yio ti dagbasoke tan. Ọkan naa yio maa mi ni iwọn igba ti o to ẹẹmẹtadinlaadọsan laarin isẹju kan.

Agbara ti ọkan ọmọ naa ni, eyiti a se akiyesi rẹ ni ọsẹ meje aabọ, fihan wipe eyi fẹrẹ ba ti agbalagba enia dọgba.

Chapter 28   Ovaries and Eyes

Bi o ba jẹ obirin, a le da apo ẹyin rẹ mọ lati ọsẹ keje.

Ni ọsẹ meje ati aabọ, ohun ti a npe ni rẹtina ninu oju ni a le se akiyesi rẹ yekeyeke, awọn ipenpeju naa si ti bẹrẹ sii ni tobi sii.

Chapter 29   Fingers and Toes

Awọn ika ọwọ wa lọtọ, awọn ọmọ-ika ẹsẹ si so pọ ni isalẹ.

Ọwọ ti S̩ee papọ soju kan, bẹẹ naa si ni ẹsẹ.

Orunkun naa ti wa nipo.

The 8-Week Embryo

Chapter 30   8 Weeks: Brain Development

Ni ọsẹ kẹjọ, ọpọlọ ti dagbasoke daada, o si jẹ iwọn idaji ninu gbogbo ara.

Idagbasoke yio maa tẹsiwaju ni kiakia.

Chapter 31   Right- and Left-Handedness

Ni ọsẹ kẹjọ, iwọn ida marundinlọgọrin ninu ọgọrun ọmọ inu oyun ni maa lo ọwọ ọtun. Awọn yoku ni a le pin si awọn ti yio lo ọwọ osi, ati awọn ti yio lo mejeeji. Eyi ni o kọkọ fi iwa lilo ọwọ ọtun tabi ọwọ osi han.

Chapter 32   Rolling Over

Iwe ẹkọ nipa ilera awọn ọmọde se apejuwe “yiyirapada ọmọde” gẹgẹbi iS̩ẹlẹ tii maa waye laarin ọsẹ kẹwa si ogun ọsẹ lẹhin ibimọ. sugbọn iru iwa ti o yanilẹnu yi ma nsaba waye nibiti agbara ti nfa ohun gbogbo walẹ ko ti pọ, ninu apo ile-ọmọ, eyiti omi kun inu rẹ. Aini agbara ti o pọ to lati bori agbara ti nfa ohun gbogbo walẹ yi ni ayika ti o yatọ si ti ile-ọmọ, ni ko le jẹki ọmọ ti a sẹsẹ bi le yi ara rẹ pada.

Ọmọ inu oyun naa ti le se ohun pupọ ni akoko yi.

O le maa yi sihin sọhun pẹlu ilọra tabi irọrun, lẹẹkọkan tabi leralera, lati inu wa tabi lairotẹlẹ.

Yiyi ori, nina ọrun, ati kika ọwọ ko sibi ori ma nwaye ni igba pupọ.

Bi a ba fọwọ kan-an, ọmọ inu oyun naa yio yara di oju rẹ, yio gbe agbọn rẹ, yio ma wa ohun ti o le dimu, yio si ma na ika ẹsẹ rẹ.

Chapter 33   Eyelid Fusion

Laarin ọsẹ keje si ikẹjọ, ipenpeju oke ati isalẹ yio bo oju ọmọ inu oyun naa, yio si so pọ ni ẹgbẹ kan.

Chapter 34   "Breathing" Motion and Urination

Biotilẹjẹpe ko si atẹgun ninu apo ile-ọmọ, ọmọ inu oyun naa yio ti bẹrẹ sii mi lati ọsẹ kẹjọ.

Ni asiko yi, kidinrin rẹ yio ti maa mu itọ jade sinu omi ti o wa ninu apo ile-ọmọ.

Ni ara ọmọ inu oyun ti o jẹ ọkunrin, koro ẹpọn ti ndagba lara rẹ yio bẹrẹ si mu ohun ti a npe ni tẹsitositẹrooni jade.

Chapter 35   The Limbs and Skin

Awọn egungun ara, orike ara, ẹran ara, isan ara, ati awọn ẹya ara ti ẹjẹ ngba san kaakiri, eyiti o wa ni ọwọ ati ẹsẹ fi ara jọ ti agbalagba.

Ni ọsẹ kẹjọ, awọ ara yio bẹrẹ si nipọn sii, ki yio si mọ gaara mọ.

Irun yio hu si oke oju ati ayika ẹnu.

Chapter 36   Summary of the First 8 Weeks

Ọsẹ kẹjọ ni opin akoko ẹmubirayoo.

Ni asiko yi,ọmọ inu oyun naa ti dagbasoke lati ẹyin kekere kanS̩oS̩o si ọkẹ aimọye ẹyin keekeke, eyiti yio di awọn orisirisi ẹya ara miran ti o le ni ẹgbẹrun mẹrin.

Ọmọ inu oyun naa ni ida aadọrun ninu ọgọrun ẹya ara agbalagba enia.


Add a Comment

Your Name: Log In 3rd-party login: Facebook     Google     Yahoo

Comment: